Idi pataki 10 lati lo Ayoba

LILO ỌFẸ

Ayoba jẹ ọfẹ lati lo. O nilo data lati fi awọn ifiranṣẹ ati faili ranṣẹ si awọn olubasọrọ rẹ, ṣugbon awọn nẹtiwọki kan (bii MTN) le fun ọ ni data naa ni ọfẹ.

KIKẸ NI PINPIN

Pin awọn fidio, aworan, ohun, ati faili miiran pẹlu awọn olubasọrọ rẹ.

ASOPỌ KIAKIA

Lo iwe adirẹsi rẹ lati sopọ ni kiakia ati irọrun mọ awọn olubasọrọ rẹ.

IPE

Ṣe awọn ipe ni inu aapu naa pẹlu asopọ ohun rẹ.

IWIREGBE NISISIYI

Fi ọrọ kikọ ati ohun ranṣẹ lojukanna si eyikeyi awon olubasọrọ rẹ.

LAILEWU

Fifi ẹnọ kọ lati ibẹrẹ de opin tumọ wipe awọn ifiranṣẹ ni inu ibaraẹnisọrọ kan ko le ṣee ka fun ẹnikẹni miiran.

SỌRỌ PẸLU GBOGBO EYAN

Fi ifiranṣẹ SMS ranṣẹ si ẹnikẹni ni inu akojọ olubasọrọ rẹ, laiwo pe won fi Ayoba si ẹrọ won tabi won ko fi si.

Ẹ JẸ KI A PADE

Pin ipo rẹ ni akoko gidi pẹlu awọn olubasọrọ Ayoba rẹ.

ẸGBẸ IBASỌRỌ

Bi ero npọ ayọ npọ! Da ẹgbẹ ibasọrọ lati ba awọn ọrẹ ati ẹbi sọrọ ni irọrun ni inu iwiregbe kanṣoṣo.

OWO FIFIRANṢẸ

Ṣe ati gba isanwo gba ọna Mobile Money (nbọ laipẹ).

Nipa wa

Ayoba jẹ aapu ifiranṣẹ lẹsẹkẹsẹ ọfẹ,

ti awon ara Afirika ṣe fun awon ara Afirika.

Biotilẹjẹpe Afirika jẹ ipin ilẹ aiye kan, o ni awọn ọgọrun lailekeji aṣa. A nkokiki oniruru Afirika nipa ọwọ pese-silẹ ẹrọ ifiranṣẹ alagbaye ti o ṣe afihan awọn aini ati ifẹ ọkan agbegbe.

Lati ibẹrẹ, Ayoba ti da fifi-ẹnọ-kọ-nkan pọ lati tọju data awọn olumulo ni aabo ati ipamọ. Eyi tumọ wipe awọn ifiranse ni inu ibaraẹnisọrọ ko le ṣee ka fun ẹnikẹni miiran, koda awon alabaṣiṣẹpọ papa ni Ayoba.

Igbesẹ alakopọ wa si tẹkinoloji tumọ wipe awọn olumulo Ayoba ma ni anfani lati ṣe ibasọrọ pẹlu ẹnikẹni to ni ẹrọ alagbeka, papa ti won ko ba tẹ tii ni aapu Ayoba.

Lọwọlọwọ bayi, Ayoba ti ṣee gbe sọkalẹ fun ẹnikẹni ti o ni ẹrọ alagbeka Android (iranlọwọ nbọ wa fun awọn iru ẹrọ iyoku!). Ni afikun, a ni ajọṣepọ onigbimọ pẹlu MTN, eyi tumọ wipe a le fun awọn onibara MTN gbogbo ni data Ayoba lọfẹ ti won ba nfi iwe, aworan, fidio ati media miiran ranṣẹ si awọn olubasọrọ won. Ni afikun, gbogbo awọn esi fun ifiranṣẹ Ayoba ma jẹ ọfe fun awọn onibara MTN, bi won nlo aapu ni o tabi won ko lo.

What’s next for Ayoba?

We have a number of exciting innovations planned for the next few months as we expand our service across Africa. This includes being able to send and receive money within Ayoba, to contacts in Africa, through Mobile Money.