Awọn ibeere loorekoore

IBẸRẸ / IBẸRẸ

Atilẹyin

Ti o ba nilo iranlọwọ tabi o fẹ kan si awọn alabaṣiṣẹ Ayoba, jọwọ lọ si Ayoba.me/contact 

Sisọ kalẹ ati fifi sori ẹrọ

Bawo ni mo ṣe sọ Ayoba kalẹ?

  • Ayoba.me/download – (data ọfẹ); tabi 

O le ṣabẹwo aaye ayelujara Ayoba lati sọ aapu naa kalẹ nigbakigba, Ti o ba jẹ olumulo MTN, o ma ni anfani lati sọ Ayoba kale ni ọfẹ, lailo data rẹ.

  • Google Play store

O tun le sọ Ayoba kalẹ lati ori Google Play Store. Ṣi Play Store naa, ki o ṣawari Ayoba, ki o sọọ kalẹ lati bẹrẹ si lo Ayoba.

Bawo ni mo ṣe ṣe imudojuiwọn Ayoba?

O le se imudojuiwọn Ayoba lori Google Play store tabi

Lọwọlọwọ nisiyi, aapu Ayoba wa fun awọn foonu Android nikan (awọn aya-ẹrọ miiran nbọ laipẹ!). Lati ṣe imudojuiwọn, lọ si ori Google Play Store, ki o tẹ Menu > My apps & games. Tẹ UPDATE ni ẹgbẹ Ayoba! Ifiranṣẹ Lẹsẹkẹsẹ Ọfẹ.

Bibẹẹkọ, lọ si Play Store ki o ṣawari Ayoba. Tẹ UPDATE ni abẹ Ayoba! Ifiranṣẹ Lẹsẹkẹsẹ Ọfẹ.

Ni ori aaye ayelujara Ayoba

O tun le ṣe imudojuiwọn aapu Ayoba rẹ ni ori aaye ayelujara wa, saati ṣabẹwo Ayoba.me/download

Bawo ni mo ṣe le fi Ayoba sori ẹrọ pada?

Lati fi aapu Ayoba sori ẹrọ pada, o nilo lati kọkọ paarẹ kuro ni ori foonu rẹ. Ṣugbọn ki o to ṣee, a ndamọran fun ọ wipe ki o ti fi ṣe afẹyinti awọn iwiregbe rẹ. Saati tẹ bọtọni menu, ki o wa yan Awọn Eto, ki o tẹ Itọju ki o wa yan Afẹyinti Iwiregbe. 

Eyi ma ṣe afẹyinti awọn iwiregbe rẹ dajudaju si inu Awọsanma, ati pe o ma fun ọ ni anfani lati mu itan iwiregbe rẹ pada wa ti o ba nilo rẹ. Ranti pe awọn afẹyinti re ko si ni ipamọ lori ẹrọ rẹ. Nitorina o ma nilo ọna iwọle si ori Intanẹẹti lati le ṣe afẹyinti.

Jọwọ tẹle awọn igbesẹ yi lati le pa Ayoba rẹ ki o tun fi sori ẹrọ pada:

Aṣayan 1:

  • Tẹ aami Ayoba ti o wa ni Iboju Ile ki o mu dani titi di igba ti awọn aami naa ngbọn
  • Tẹ X ti o wa ni igun aami Ayoba naa
  • Tẹ Paarẹ lati yọ aapu naa kuro pẹlu awọn data rẹ gbogbo
  • Te bọtọni Ile
  • Tun sọ Ayoba kalẹ lati ori Google Play Store.
  • Tẹ bọtọni menu lati mu Afẹyinti Iwiregbe rẹ pada wa, ki o wa yan Awọn Eto, ki o wa tẹ Itọju ati ki o yan Afẹyinti Iwiregbe, ati mu padawa.
  • O tun le ṣabẹwo aaye ayelujara Ayoba lati sọ aapu naa kalẹ nigbakigba. Ti o ba jẹ olumulo MTN, o ma ni anfani lati sọ Ayoba kale ni ọfẹ*, lailo data rẹ.

*Ni igba ipolowo

Aṣayan 2:

  • Tẹ aami Ayoba ti o wa ni Iboju Ile ati ki o mu dani, ki o wa faa bọlẹ si inu apoti idọti/apoti yọọ-kuro-lori-ẹro
    • Yan yọọ-kuro-lori-ẹro lati jẹrisi piparẹ aapu naa pẹlu awọn data rẹ gbogbo
    • Te bọtọni Ile
    • Tun sọ Ayoba kalẹ lati ori Google Play Store.
  • Tẹ bọtọni menu lati mu Afẹyinti Iwiregbe rẹ pada wa, ki o wa yan Awọn Eto, ki o wa tẹ Itọju ati ki o yan Afẹyinti Iwiregbe, ati mu padawa.
  • O tun le ṣabẹwo aaye ayelujara Ayoba lati sọ aapu naa kalẹ nigbakigba. Ti o ba jẹ olumulo MTN, o ma ni anfani lati sọ Ayoba kale ni ọfẹ*, lailo data rẹ.

*Ni igba ipolowo

Ijẹrisi

Bawo ni mo ṣe jẹrisi nomba mi?

Ti o ba ti sọ aapu naa kalẹ, ṣii ki o wa tẹle awọn igbesẹ yi:

  1. Fi gbogbo orukọ rẹ sii 
  2. Yan orilẹ-ede rẹ ni inu akojọ to nbọlẹ naa. Eyi o ma fi koodu orilẹ-ede fun foonu si laifọwọyi
  3. Fi nọmba foonu rẹ si inu apoti ti o wa ni isalẹ
  4. Tẹẹ lati beere koodu kan
  5. Fi koodu oni-ika-6 ti o gba nipasẹ SMS si

Mi o gba koodu oni-ika-6 kan nipasẹ SMS o

  • Duro ki aago kika sẹhin naa tan ki o wa yan Fi SMS Ranṣẹ lẹẹkansi.
  • Ma ṣe ṣi koodu naa kọ, bibẹkọ won ma ti ọ sita akanti rẹ fun akoko melo kan. Eyi jẹ aabo fun akanti rẹ ki ẹnikẹni miiran ma le wọ inu ẹ. 

Ti awọn iṣoro naa ba ntẹsiwaju, jọwọ gbiyanju ni inu awọn igbesẹ yi:

  • Ṣe atunbẹrẹ foonu rẹ (lati ṣe atunbẹrẹ foonu, paa, duro fun ọmọ-ẹhin isẹju 30, ki o wa tun tan).
  • Paarẹ ki o wa fi ẹya Ayoba ti ikẹhin si ori ẹrọ.

Njẹ mo le lo Ayoba ni ori ẹro meji?

Ori nomba kanṣoṣo lori ẹrọ kanṣoṣo ni o le ṣe ijẹri akanti Ayoba rẹ. Ti o ba ni foonu oni SIM meji, jọwọ ranti pe o gbọdọ yan nomba kanṣoṣo lati fi ṣe ijẹri pẹlu Ayoba. Ko si aṣayan ini akanti Ayoba kan pẹlu nomba foonu meji.

Ṣe mo nilo lati forukọsilẹ lẹẹkansi ti mo ba yọ aapu naa kuro lori ẹrọ ti mo tun fisii pada?

Rara o. Gbogbo ohun ti o nilo lati ṣe ni ki o sọ Ayoba kalẹ lati ori Google Play Store lẹẹkansi tabi lati ori Ayoba.me/download. Fi orukọ rẹ sii, yan orilẹ-ede rẹ ni inu menu to nbọlẹ naa, fi nomba foonu rẹ sii ki o wa yan Ijẹrisi.

Akiyesi: ti o ba ti ṣe afẹyinti itan iwiregbe rẹ ki o to pa aapu naa rẹ ati fi sori ẹrọ pada, itan iwiregbe rẹ yoo pada wa laifọwọyi.

LILO AYOBA

Iṣakoso Akanti ati Profaili

Bawo ni mo ṣe fi aworan profaili mi sii tabi ṣe imudojuiwọn rẹ?

Ti o o ba tii yan aworan profaili:

  1. Ṣii menu ni apa osi oke ti aapu naa
  2. Tẹ aami iṣatunṣe
  3. Tẹ aworan profaili > aami kamẹra
  4. Yan aworan kan lati le lo fun aworan profaili rẹ

Ti o ba ti ni aworan profaili tẹlẹ:

  1. Ṣii menu ni apa osi oke ti aapu naa
  2. Tẹ aworan profaili rẹ tabi aami iṣatunṣe
  3. Ti o ba nyan aami iṣatunṣe, nigbana tẹ aworan profaili rẹ > aami kamẹra
  4. Yan aworan kan lati le paro aworan profaili rẹ ti isiyi

Njẹ mo le ṣe imudojuiwọn Orukọ Ifihan mi?

  1. Ṣii menu ni apa osi oke ti aapu naa
  2. Tẹ Orukọ Ifihan rẹ tabi aami iṣatunṣe, ki o wa ṣe atunṣe tabi ifikun orukọ ifihan titun rẹ 

Bawo ni mo ṣe fi ipo mi sii tabi ṣe imudojuiwọn rẹ?

  1. Ṣii menu ni apa osi oke ti aapu naa
  2. Tẹ ipo rẹ tabi aami iṣatunṣe
  3. Fi ipo tintun sii ki o wa yan aami ijẹrisi, tabi ki o yan ipo kan ni inu akojọ awọn ipo rẹ ti tẹlẹ

Akiyesi: Ti o ba dina fun olubasọrọ kan, ẹni naa ko ni le ri aworan profaili rẹ tabi awọn imudojuiwọn ipo rẹ

Bawo ni mo ṣe pa akanti mi rẹ?

Awọn igbesẹ ti o rọrun diẹ wa lati tẹle ti o ba pinnu lati pa akanti rẹ rẹ. Ṣe akiyesi pe ilọsiwaju yii ko le ṣe yipada ni inu ọran kankan, koda koleṣeṣe fun alabaṣiṣẹ Ayoba kan, nitorina jọwọ rii daju pe eyi jẹ ohun ti o fẹ ṣe.

Tẹle awọn igbesẹ mẹrin yi:

  1. Ṣi aapu Ayoba naa
  2. Ṣii menu ni apa osi oke ti aapu naa
  3. Tẹ Awon Eto > Itọju > Pa akanti rẹ rẹ
  4. Tẹ OK ki o fi jẹrisi

Piparẹ akanti rẹ ma:

  • Pa akanti Ayoba rẹ rẹ laiyẹsẹ
  • Nu itan ifiranṣẹ rẹ kuro
  • Mu ọ kuro ni inu awọn ẹgbẹ Ayoba gbogbo lẹsẹkẹsẹ

Awọn nkan pataki melo kan ti eyan lati ṣe akiyesi:

  • O o ni le ri ọna wọle si inu akanti rẹ
  • Piparẹ akanti rẹ ko ni ipa lori awọn iwifun ti awọn olumulo miiran ni nipa iwọ, bii kikọ awọn ifiranṣẹ ti won ti fi ranṣẹ si ọ
  • Kikọ awọn ohun elo melo kan (bii awọn akọsilẹ iwọle ati ijade) le ku ni inu ibi ipamọ data wa ṣugbọn won ya sọtọ si awọn idanimọ ti ara ẹni.

Ṣe mo le lo Ayoba lori foonu titun mi?

To ba jẹ pe o nkuro lori foonu kan si ori omii, ti o ntọju nọmba rẹ, o ma tọju gbogbo awọn iwifun akanti rẹ. Nọmba foonu ni awọn iwifun akanti so mọ. Saati sọ Ayoba kalẹ si ori foonu tintun naa ki o jẹri nọmba rẹ.

To ba jẹ pe o nkuro lori foonu kan si ori omii, ti o o si tọju nọmba rẹ, sọ Ayoba kalẹ si ori foonu tintun naa ki o jẹri nọmba tintun naa.

Bawo ni mo ṣe parọ ede lori Ayoba?

Lati parọ ede foonu rẹ:

Android: Ni inu foonu rẹ, lọ si Awọn Eto > Sisitẹmu > Awoọn Ede & igbewọle > Awọn Ede. Tẹẹ ki o yan ede kan.

To ba jẹ pe foonu Android ni o nlo, o tun le yi ede Ayoba pada lati inu aapu. Lati le ṣe, saati tẹ menu ki o yan Awon Eto ki o wa tẹ Itoju.

IFOWOLERI/ AWON IYE OWO

Awon iye owo olumulo Ayoba

Elo ni ọrọ tabi faili media fifiranṣẹ lori Ayoba? 

Ayoba nlo asopọ Intanẹẹti rẹ (4G/3G/2G/EDGE tabi Wi-Fi) fun fifiranṣẹ ati gbigba awọn ifiranṣẹ si awọn ọrẹ ati ẹbi rẹ. Iye owo data ti o lo fi ṣe fifiransẹ ati gbigba awon ifiranṣẹ ma gbarale ṣiṣe-alabapin ti o ni pẹlu olupese iṣẹ rẹ. O tun gbọdọ rii daju pe o o koja ala data rẹ. Bakanna, o tun le lo Ayoba ni igba ti o ṣe asopọ mọ nẹtiwọki Wi-Fi, eyi jẹ ọfẹ.

Ayoba ti ṣe alabaṣepọ pẹlu MTN, ẹlẹrọ alagbeka ti o tobi julọ ti ilẹ Afirika, lati pese data Ayoba lọfẹ* fun awọn onibara MTN (eyi gbarale awọn ilana nipa lilo ẹtọ). Eyi tumo wipe awọn onibara MTN ma ni anfani lati ṣe fifiranṣẹ ati gbigba ọrọ kiko, ohun gbigbo, fidio, aworan ati faili ni inu aapu Ayoba laisanwo kan kun.

*Ni igba ipolowo

Elo ni lati fi ṣe awon ipe ohun lori Ayoba?

O le ṣe awọn ipe ohun lati ori aapu Ayoba si ẹnikẹni awọn olubasọrọ Ayoba rẹ. Iye owo ti o ma san fun ipe naa ma jẹ iye kanna pẹlu ipe ohun deedee ati pe ipe naa ma lo awon iṣẹju ti o ti ra kalẹ. Pataki julọ, ipe ṣiṣe ni inu aapu naa kiyi lo data kan, ati pe kiyi ṣe ọfẹ.

Ifowoleri fun awon olumulo ti ko si lori Ayoba.

Ṣe mo nilo aapu Ayoba dandan ni lati ṣe fifiranṣẹ ati gbigba ifiranṣẹ pẹlu awọn ọrẹ ati ẹbi ti won nlo Ayoba ni?

Ayoba maa ṣiṣẹ daradara julọ nigbati o ba nsọrọ pẹlu ẹlomiran ti o ni Ayoba lori foonu rẹ. Ṣugbọn, a ṣe iyanju pataki kan lati fa gbogbo eyan mọra, laise bii awọn aapu ifiranṣẹ miiran, a fun ọ ni anfani lati sọrọ pẹlu ẹnikẹni ti o ni aapu Ayoba tabi ti ko ni.

Awọn ifiranṣẹ ti o ṣe gba ori Ayoba si awọn olubasọrọ rẹ ti ko ni aapu Ayoba ma bọ si ọwọ won bii ifiranṣẹ SMS, ni won ma ni awon ọna asopọ lati le wo aworan tabi faili ni inu aṣawakiri won.

Ni ọpọlọpọ awọn orilẹ-ede, ajọṣepọ wa pẹlu MTN tumọ wipe bi olubasọrọ rẹ ba jẹ onibara MTN, won le lo SMS fi dahun si ifiranṣẹ rẹ ni iwọ ma gba esi naa lẹsẹkẹsẹ ni inu aapu Ayoba rẹ. Ajọṣepọ wa pẹlu MTN tun tumọ wipe gbogbo awọn esi SMS naa ma je ọfẹ.

Sibẹsibẹ, bi olubasọrọ rẹ ko jẹ onibara MTN, won tun maa ni anfani lati gba awọn ifiranṣẹ gba ọna SMS, ṣugbọn won ko ni le fun esi. Won ma gba alaye nipa idiwọn yen. Ojutu ti o dara ju ni igba yen ni ki awọn olubasọrọ sọ aapu Ayoba kalẹ.

Elo ni bi mi o ba ni Aapu Ayoba lori ẹrọ mi?

Ti o ba jẹ onibara MTN, ti o o ni aapu Ayoba lori foonu rẹ, o tun le dahun si ifiranṣẹ SMS ti o gba lati ọdọ olumulo Ayoba ati pe esi SMS rẹ ma jẹ ọfẹ.

Ti iwọ ko ba jẹ olumulo MTN, o ma gba awọn ifiranṣẹ Ayoba gba ọna SMS ṣugbọn iwọ ko ni le fun esi. Sọ aapu naa kalẹ lati ori Play Store tabi ni Ayoba.me/download ki o maa gbadun iriri Ayoba.

Won ma fun yin ni data ọfẹ fun igba ipolowo ni abẹ ilana nipa lilo ẹtọ.

Ti o ba jẹ onibara MTN, o le so Ayoba kale ni ofe nisiyi ni Ayoba.me/download. Tabi o le ṣabẹwo ni Google Play Store.

AABO

Ṣe lilo Ayoba ni aabo?

Lati tọju data rẹ ni aabo ati lati bo awọn aṣiri rẹ, Ayoba da fifi-ẹnọ-kọ-nkan pọ. Eyi ndaniloju wipe iwọ nikan ati ẹni (tabi awọn ẹni) ti o nbasọrọ nikan ni won le ka nkan ti ẹ firanṣẹ si arayin. Ko si ẹnikẹni miiran to le kaa, koda ko le ṣeṣe fun awon alabaṣiṣẹpọ Ayoba papa.

A maa ran ọ leti pe a o ni pin awọn alaye rẹ pẹlu ẹnikẹni miiran layi gba aṣẹ lọwọ rẹ. O le ṣakoso Awọn Eto Ipamọ ni inu aapu naa: yan Fifiranṣẹ lati inu menu Awọn Eto, ki o wa tẹ Ipamọ. A tun damọran fun ọ wipe ki o ṣe ayẹwo ilana wa nipa Ipamọ ni Ayoba.me/termsandconditions.

Awọn foonu ti o sọnu ati eyi ti won ji

Foonu mi sọnu, kini mo gbọdọ ṣe nisiyi?

  • Ti foonu rẹ ba sọnu tabi won ji, a le ran ọ lọwọ lati fi akanti Ayoba rẹ si aabo lati dina fun lilo laigba aṣẹ. Jọwọ tẹle awọn igbesẹ to wa ni isalẹ
  • A tun ndamọran fun ọ wipe ki o pe olupese alagbeka rẹ lẹsẹkẹsẹ lati ti kaadi SIM rẹ pa, ki ẹlomiran maṣe le lo foonu rẹ. Nigbati won ti ti SIM naa pa, o o ni le ṣe ayẹwo akanti Ayoba rẹ pẹlu nomba yen, nitori pe o gbọdọ gba SMS fi ṣe ayẹwo tan.

Aṣayan meji lo wa:

  • Lo kaadi SIM tintun pẹlu nomba kanna fi mu Ayoba ṣiṣẹ lori foonu tintun rẹ. Eyi ni ọna ti o yara julọ lati fi da akanti rẹ niṣẹ duro lori foonu to sọnu naa. Ayoba le ṣiṣẹ pẹlu nomba foonu kanṣoṣo lori ẹrọ kanṣoṣo.
  • Kan si wa ni Ayoba.me/help ki o fọwọsi fọọmu esi naa pẹlu gbolohun “foonu ti o sọnu/ti won ji ni inu akọle. Ẹ jọwọ, ẹ daṣẹ duro fun akanti mi” ati ki o wa fi nomba foonu rẹ sii ni ọna kika agbaye bi ti won ṣe ṣalaye nibi.

Akiyesi: 

O ṣe pataki ki o ranti wipe bi won ba ti kaadi SIM rẹ pa, ti ẹnikan ba le ri ọna wọ inu foonu rẹ ati aapu Ayoba naa, ẹni naa le loo lori Wi-FI. Ile-iṣẹ Ayoba ko ni agbara lati da iṣẹ duro fun Ayoba lati okere. Nitorina a ndamọran fun ọ pe ki o kan si wa lati tete da iṣẹ duro fun akanti rẹ.

Ṣe akiyesi wipe ile-iṣẹ Ayoba ko ni ọna lati mọ ipo foonu rẹ bakanna a o le ran ọ lọwọ lati mọ ipo foonu. Foonu naa le ni aapu kan to le ṣe iranlọwọ fun ọ lati ṣiṣẹ yen gba ori ẹrọ miiran..

Ti o ba ti ṣe afẹyinti iwiregbe ki foonu rẹ to sọnu, o le ni anfani lati mu itan iwiregbe rẹ pada wa.

  • Awon afẹyinti maa ṣẹlẹ laifọwọyi ni gbogbo wakati 24-24, gba ọna asopọ intanẹẹti.
  • Awon olumulo o ni agbara lati mu afẹyinti naa ṣiṣẹ tabi da ni iṣẹ duro.
  • Nkan ti awon olumulo le ṣe nikan ni ki won da afẹyinti tintun silẹ. Lati ṣe, won ma tẹ: “Menu” > Awon Eto > “Itọju” > “Afẹyinti Iwiregbe”.
  • Akanti kọkan ni afẹyinti kan, ti o ba da Afẹyinti Iwiregbe kan silẹ, afẹyinti ti tẹlẹ naa ma parẹ.
  • Igba kanṣoṣo ti awọn afẹyinti maa padawa ni ẹhin igba iwọle/iforukọsilẹ! Lẹẹkanna lẹhin afọwọsi OTP.

Aabo rẹ

Ṣe mo le fẹjọsun nipa awọn ito ti ko yẹ?

A fẹ ṣe-daju fun ọ nigbagbogbo nipa aabo rẹ, jọwọ fẹjọsun nipa ito tabi aṣa ti ko yẹ ni Ayoba.me/contact, ki o yan aṣayan “Fẹjọsun nipa ito ti ko yẹ”. A ma ṣe iwadi ati igbesẹ ti o yẹ.

Ṣe akiyesi wipe o le ṣe ki a ma ni anfani lati pin awọn esi iwadi naa pẹlu rẹ, ṣugbon a ṣe-daju pe awọn ifẹjọsun gbogbo ni o jẹ pataki fun wa.

Ṣe mo le kọ ifẹjọsun silẹ nipa olumulo kan?

Aabo awọn olumulo wa jẹ nkan pataki fun wa gan ati pe a o yi gba awọn aṣa buruku lati ọwọ awọn olumulo. Jọwọ lo si Ayoba.me/contact, ki o yan aṣayan “Fẹjọsun nipa olumulo kan”. A ma ṣe iwadi ati igbesẹ ti o yẹ.

Ṣe akiyesi wipe o le ṣe ki a ma ni anfani lati pin awọn esi iwadi naa pẹlu rẹ ṣugbon a ṣe-daju pe awọn ifẹjọsun gbogbo ni o jẹ pataki fun wa.

IWIREGBE LORI AYOBA

Njẹ mo le pin awọn alaye olubasọrọ ti awọn olubasọrọ mi nigbati mo nlo Ayoba?

Bẹẹni o le ṣe! Lo + (aami iwiregbe tintun) lati bẹrẹ iwiregbe tintun kan, ni ki o wa tẹ aami asomọ, nigbana o le yan Olubasọrọ, ni ki o wa tẹ olubasọrọ ti o fẹ pin naa.

Njẹ mo le fi aworan ranṣẹ nigbati mo nlo Ayoba?

Pin awọn aworan ayanfẹ rẹ ni irọọrun pẹlu Ayoba. Lo + (aami iwiregbe tintun) lati bẹrẹ iwiregbe tintun kan, ni ki o wa tẹ aami asomọ, nigbana o wa yan Ipo-Aworan fi yan awon aworan. O tun le tẹ Kamera lati fi ya aworan ati pin i lẹsẹkẹsẹ.

Njẹ mo le pin ipo mi nigbati mo nlo Ayoba?

Pin ipo rẹ pẹlu awọn olubasọrọ rẹ: saa ti tẹ + (aami iwiregbe tintun) lati bẹrẹ iwiregbe tintun kan, ni ki o wa tẹ aami asomọ ati ki o wa yan Ipo.

Njẹ mo le fi ifiranṣẹ olohun ranṣẹ nigbati mo nlo Ayoba?

O le fi ifiranṣẹ ohun kekere kan ranṣẹ si olumulo Ayoba miiran: saa ti tẹ aami gbohungbohun ni isalẹ apa otun iboju iwiregbe rẹ. O tun le da ifiranṣẹ iwiregbe tintun: lo + (aami iwiregbe tintun) ki o wa tẹ aami asomọ ati ki o wa yan Ohun, nigbana o wa tẹ aami Gbohungbohun ni o wa gba ohun ifiranṣẹ naa.

Mo nilo lati fi faili tabi iwe-iṣẹ ranṣẹ, ṣe mo le lo Ayoba?

Tẹ + (aami iwiregbe tintun) lati bẹrẹ iwiregbe tintun ki o fi fi awọn faili ranṣẹ, nigbana te aami asomọ ki o wa yan Faili. Nisiyi kiri gba inu ẹrọ rẹ, yan faili naa ki o wa pin pẹlu awon onibasọrọ rẹ.

Bawo ni mo ṣe le dahun si awọn ifiranṣẹ?

Tẹ ifiranṣẹ ti o fẹ wo. Lati fun esi, saa ti tẹ ipo iwe kikọ ni isalẹ iboju rẹ ni ki o wa tẹ esi rẹ si ati ki o firanṣẹ. Bẹẹni o rọrun to.

Njẹ mo le pin awọn ifiranṣẹ tabi ki nju ranṣẹ si awọn olubasọrọ Ayoba mi?

O le ju ifiranṣẹ, faili ohun, aworan ati olubasọrọ ranṣẹ: tẹ nkan ti o fẹ ju ranṣẹ ki o mu dani, nigbana tẹ aami juranṣẹ ni oke apa ọtun iboju re, ni ki o wa yan olubasọrọ ti o fẹ juu ranṣẹ si ki o wa te firanṣẹ. Won ma kọ “Ti juu ranṣẹ” si ara ifiranṣẹ naa. O tun ma gba iwifunni wipe won ti ju ifiranṣẹ naa ranṣẹ.

Bawo ni mo ṣe le pa awọn ifiranṣẹ atijọ tabi aifẹ rẹ?

Tẹ ifiranṣẹ naa ni inu iboju iwiregbe, ki o mu dani, nigbana yan aami igba idọti ni oke iboju naa, nikẹyin ki o wa jẹrisi aṣayan rẹ. 

Njẹ mo le ko awọn iwiregbe mi lọ si akojọ ipamọ?

Rara o, Ayoba ko ni ọna lati ko awọn iwiregbe lọ si akojọ ipamọ (ni akoko yi). Ti o ba fẹ ko iwiregbe kan kuro ni inu akojọ iwiregbe rẹ, o le paarẹ, sugbọn iparẹ patapata niyẹn, o o ni anfani lati gba pada mọ.

Njẹ mo le to awọn iwiregbe mi lẹsẹẹsẹ si ọna oriṣiriṣi?

Awọn iwiregbe rẹ wa ni tito lẹsẹẹsẹ nigbagbogbo nipasẹ awọn eyi to jẹ tintun julọ, awọn eleyi maa han ni oke akojọ naa. O o le parọ ọwọ tito yi ni inu Ayoba (ni akoko yi).

Bawo ni mo ṣe le pa awọn iwiregbe rẹ?

Ni inu iboju Ayoba olori naa, tẹ iwiregbe ti o fẹ parẹ naa ki o mu dani, nigbana wa yan aami igba idọti ni oke iboju naa, ni ki o wa jẹrisi aṣayan rẹ.

Bawo ni mo ṣe le da ẹgbẹ iwiregbe ati pe awon olubasoro wa si inu rẹ?

Tẹ bọtini iwiregbe tintun + ni ki o yan aṣayan ẸGBẸ TINTUN, nigbana fi awọn olubasọrọ ti o fẹ kun si inu ẹgbẹ iwiregbe rẹ. Nisiyi nkan ti o ku nikan ni ki o bẹrẹ ibaraẹnisọrọ naa.

Bi mo ba fẹ kuro ni inu ẹgbẹ iwiregbe kan nkọ?

O le jade kuro ni inu ẹgbẹ iwiregbe eyikeyi nigba eyikeyi: saa ti tẹ aami ẹgbẹ iwiregbe ni oke iboju iwiregbe rẹ, nigbana o wa tẹ bọtọni KURO NINU ẸGBẸ, ni ki o wa jẹrisi aṣayan rẹ.

Bi mo ba fẹ pa ẹgbẹ iwiregbe kan rẹ nkọ?

Ti o ba fẹ pa iwiregbe ẹgbẹ rẹ, saa ti tẹ iwiregbe ẹgbẹ naa ninu iboju olori ki o mu dani, nigbana yan igba idọti, ni ki o wa jẹrisi aṣayan rẹ. O tun le yan lati jade kuro ninu ẹgbẹ naa nigba yẹn.

Ti o ba pa iwiregbe ẹgbẹ kan rẹ, awọn ọrọ ẹgbẹ naa nikan ni o parẹ kuro lori ẹrọ rẹ, o o pa iwiregbe naa rẹ kuro fun awọn ara ẹgbẹ titọhun o.

Kini Olu Ẹgbẹ maa ṣe?

Olu ẹgbẹ le da ẹgbẹ kan, fi awon ara-ẹgbẹ kun tabi ki o pa won rẹ

Njẹ mo le sọ elomiiran di Olu Ẹgbẹ?

Iṣakoso ko le ṣe gbe fun elomiiran

Njẹ a le ni ju Olu Ẹgbẹ kan lọ?

Ẹ ko le ni eyan pupo ni ipo Olu Ẹgbẹ o

Won fi mi kun ẹgbẹ kan, njẹ mo le ri iwiregbe ti won ti ṣe kọja?

Ti won ba fi ọ kun ẹgbẹ kan, o o ni le ri awọn ifiranṣẹ ati iwiregbe ti won ṣe ki o to darapọ mọ ẹgbẹ naa

Bi mo ba fẹ mu itan iwiregbe mi pada sipo nkọ?

Awon afẹyinti maa ṣẹlẹ laifọwọyi ni gbogbo wakati 24-24, ti o ba ni asopọ intanẹẹti. O o ni agbara lati mu afẹyinti laifọwọyi naa ṣiṣẹ tabi da ni iṣẹ duro.

O ma ni anfani lati fi agbara da afẹyinti tintun silẹ: tẹ ipo Menu, yan Awọn Eto, ati Itọju ati Afẹyinti Iwiregbe. Eyi ma mu awọn iwiregbe rẹ fẹyinyi ni aabo, ati pe o ma fun ọ ni anfani lati mu itan iwiregbe rẹ pada sipo bi o ba fẹ.

Lati mu Afẹyinti Iwiregbe rẹ pada sipo: tẹ bọtọni menu, yan Awon Eto, nigbana tẹ Itọju, ki o wa yan Afẹyinti Iwiregbe, ati mu pada sipo.

Ṣe akiyesi pe awọn afẹyinti rẹ ko si ni ipamọ ni agbegbe lori ẹrọ rẹ, nigbana o ma nilo ọna iwọle de ori Intanẹẹti lati ṣe afeyinti.

Njẹ mo le mu Igbesọkale Laifọwọyi awọn faili ti won firanṣẹ si mi ṣiṣẹ?

Ẹya Isọkalẹ Laifọwọyi maa wa lori ọwọ PIPA. Ti o ba fẹ sọ awọn aworan ati fidio kalẹ laifọwọyi, o le TAN Isọkalẹ Laifọwọyi. O le fi isẹ si ẹya Isọkalẹ Laifọwọyi gba inu menu olori, ki o wa tẹ Media ati ki o wa ṣe eto isọkalẹ laifọwọyi bi ti o ṣe nilo rẹ. Imọran tiwa ni wipe ki o paa bi o o ba ni data pupọ.

Iwiregbe pẹlu awọn ẹni ti ko yi ṣe olumulo Ayoba

Njẹ mo le ṣe iwiregbe pẹlu awọn ẹni ti ko ni aapu Ayoba?

O le fi ifiranṣẹ ranṣẹ si ẹnikẹni gba ori Ayoba, koda bi won ko ba ni aapu naa ni ori ẹrọ won. Awọn ifiranṣẹ ti won firanṣẹ si awọn ẹni ti won ko sọ Ayoba kalẹ ati ti won forukọsilẹ si ma bọ si ọwọ won bii ifiranṣẹ SMS, ni won ma ni awon ọna asopọ lati le wo awon faili ati nkan ti won firanṣẹ si won.

A ṣe alabaṣepọ pẹlu MTN, eyi tumọ wipe awọn onibara MTN ma ni anfani lati lo SMS fi dahun si awọn ifiranṣẹ SMS ti Ayoba, ni ọfẹ, koda bi won ko ba ni aapu Ayoba lori ẹrọ won. Awọn ẹni ti won ko yi ṣe onibara MTN ma gba awọn ifiranṣẹ lati Ayoba gba ọna SMS, ṣugbọn won ko ni le fun esi. A ndamọran wipe ki awọn ẹni ti won ko yi ṣe onibara MTN ki won sọ aapu Ayoba kalẹ ni ọfẹ lati Ayoba.me/download tabi Google Play Store 

Njẹ mo le fi awọn olubasọrọ kun, koda bi won ko lo Ayoba?

Nigbati o nda iwiregbe tintun silẹ, tẹ menu ni kọrọ oke apa otun. Nigbana mu Fi Awọn Olubasọrọ SMS Han ṣiṣẹ. O ma ni anfani lati ri gbogbo awon olubasọrọ, papa awon eyi ti won ko lo aapu Ayoba.

Ti ẹnikẹni ninu awọn olubasọrọ naa ba sọ aapu Ayoba kalẹ ati won forukọsilẹ pẹlu nomba foonu ti o wa ninu akojọ olubasọrọ rẹ, aapu Ayoba naa ma ṣe imudojuiwọn ipo won laifọwọyi lati fi han ọ wipe won le ba ọ sọrọ nipa olumulo Ayoba gidi.

Njẹ mo le fi aworan tabi faili ranṣẹ si awọn olubasọrọ ti won ko sọ aapu Ayoba kalẹ?

O le fi aworan, fidio ati ọna asopọ ranṣẹ si awọn olubasọrọ ti won ko sọ aapu Ayoba kalẹ. Awọn olubasọrọ yi ma gba iwifunni SMS ti o ni ọna asopọ lati wo ifiranṣẹ naa. Ṣe akiyesi pe riri tabi sisọkalẹ ifiranṣẹ naa le mu won na owo fun olupese nẹtiwọki won.

Mo gba ifiranṣẹ Ayoba kan, ṣugbon mi o ni aapu naa. Njẹ mo le ri ifiranṣẹ yẹn wo?

O le ri awọn ifiranṣẹ ati faili ti awọn olumulo Ayoba firanṣẹ si ọ gba ori Ayoba, papa ti o o ba ti sọ aapu Ayoba naa kalẹ ni ọfẹ. A ṣe alabaṣepọ pẹlu MTN, eyi tumọ wipe awọn onibara MTN ma ni anfani lati lo SMS fi dahun si awọn ifiranṣẹ SMS ti Ayoba, ni ọfẹ, koda bi won ko ba ni aapu Ayoba lori ẹrọ won. Awọn ẹni ti won ko yi ṣe onibara MTN ma gba awọn ifiranṣẹ lati Ayoba gba ọna SMS, ṣugbọn won ko ni le fun esi. A ndamọran wipe ki awọn ẹni ti won ko yi ṣe onibara MTN ki won sọ aapu Ayoba kalẹ ni ọfẹ lati Ayoba.me/download tabi Google Play Store.

IṢAKOSO AWỌN OLUBASỌRỌ RẸ

Bawo ni mo ṣe le fi olubasọrọ kun?

Kan fi nomba olubasọrọ naa kun awọn olubasọrọ ti foonu rẹ. Nigbana o wa ṣi aapu Ayoba naa, ni o wa tẹ aami ifiranṣẹ tintun + ni o wa yan olubasọrọ ti o fẹ ba ṣe iwiregbe.

Aapu Ayoba naa ma fihan laifọwọyi bi olubasọrọ naa ba ti ṣe sisọkalẹ ati iforukọsilẹ nomba rẹ pẹlu Ayoba. Bi ko tii ṣee, won ma fihan bii olubasọrọ SMS lasan ninu Ayoba.

Bawo ni mo ṣe le pa awọn olubasọrọ rẹ?

O le pa awọn olubasọrọ rẹ deede gba inu aapu olubasọrọ foonu rẹ. Ṣi akojọ olubasọrọ foonu rẹ, tẹ orukọ olubasọrọ naa ati ki o tẹ menu ni oke apa ọtun. Yan paarẹ, ati ki o jẹrisi aṣayan rẹ.

Bawo ni mo ṣe le dina fun olubasọrọ kan?

O le dina fun olubasọrọ ninu Ayoba: da iwiregbe tintun silẹ ati ki o tẹ aami menu ni oke ọwọ ọtun. Yan Dina, ni ki o jẹrisi igbesẹ rẹ. Ti o ba dina fun olubasọrọ kan, o o tun le gba ifiranṣẹ kankan lati ọdọ olubasọrọ naa, ni ohun naa ko ni le ri ipo rẹ. O maa ri orukọ rẹ ninu akojọ olubasọrọ rẹ, ṣugbọn yo ti gba aami “Ti Dina Fun”. Bi o ba fẹ wa fi ifiranṣẹ si olubasọrọ ti o ti dina fun, o ma nilo lati ṣina fun u.

A fẹ rii daju nipa aabo rẹ nigbagbogbo, nitorina jọwọ fẹjọsun nipa iwa tabi ifiranṣẹ ti ko tọ ni Ayoba.me/contact, tabi ki o kan si <Security FAQ section> nibi

Bawo ni mo ṣe le ṣina fun olubasọrọ ti mo ti dina fun tẹlẹ?

O le ṣina pada fun olubasọrọ ti o ti dina fun tẹlẹ gba ori ọwọ yi: da iwiregbe tintun silẹ pẹlu ilo aami +, yan olubasọrọ naa, lo menu ni oke apa ọtun ati ki o tẹ Ṣina Fun, ni ki o wa jẹrisi igbesẹ rẹ. Nisiyi o ma ni anfani lati ba olubasọrọ naa ṣe iwiregbe, ni ohun naa o le maa fi nkan ranṣẹ si ọ, ki o maa fun ọ ni esi ati ki o maa ri ipo rẹ.

Bawo ni mo ṣe le ṣe ipe ohun lori Ayoba?

O le ṣe ipe ohun lati inu aapu Ayoba si ẹnikẹni awọn olubasọrọ Ayoba re. Ipe naa yoo jẹ iye owo ipe ohun lasan ni yoo lo awọn iṣẹju ti o ti ra kalẹ. Pataki julọ, ipe ṣiṣe ninu aapu naa kiyi lo data ati kiyi ṣe ọfẹ. Lati ṣe ipe ohun pẹlu Ayoba, tẹ (aami iwiregbe tintun) + ati ki o tẹ aami foonu ti won fi nṣe ipe ohun.